1 Ọba 9:23-28
23
Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Solomoni, àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀ta (550), ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà.
24
Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Farao ti gòkè láti ìlú Dafidi wá sí ààfin tí Solomoni kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Millo.
25
Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Solomoni ń rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún Olúwa, ó sì sun tùràrí níwájú Olúwa pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà.
26
Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa.
27
Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni.
28
Wọ́n sì dé Ofiri, wọ́n sì mú irinwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings