Hoppa till innehåll
1 Ọba 13:11-17

1 Ọba 13:11-17

11
Wòlíì àgbà kan wà tí ń gbé Beteli, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé, tí ó sì ròyìn gbogbo ohun tí ènìyàn Ọlọ́run náà ti ṣe ní Beteli ní ọjọ́ náà fún un. Wọ́n sì tún sọ fún baba wọn ohun tí ó sọ fún ọba.
12
Baba wọn sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ọ̀nà wo ni ó gbà?” Àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi ọ̀nà tí ènìyàn Ọlọ́run láti Juda gbà hàn án.
13
Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un tán, ó sì gùn ún.
14
Ó sì tẹ̀lé ènìyàn Ọlọ́run náà lẹ́yìn. Ó sì rí i tí ó jókòó lábẹ́ igi óákù kan, ó sì wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá bí?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.”
15
Nígbà náà ni wòlíì náà sì wí fún un pé, “Bá mi lọ ilé, kí o sì jẹun.”
16
Ènìyàn Ọlọ́run náà sì wí pé, “Èmi kò le padà sẹ́yìn tàbí bá ọ lọ ilé, tàbí kí èmi kí ó jẹ oúnjẹ tàbí mu omi pẹ̀lú rẹ níhìn-ín.
17
A ti sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi níhìn-ín tàbí kí o padà lọ nípa ọ̀nà tí ìwọ bá wá.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options