1 Johanu 2:13-17
13
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe, Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà.
14
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n, nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètèkọ́ṣe. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ni agbára, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín, tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.
15
Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀.
16
Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.
17
Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings