1 Kọrinti 15:53-57
53
Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀.
54
Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.”
55
“Ikú, oró rẹ dà? Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?”
56
Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin.
57
Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!
Settings