Skip to content
1 Kọrinti 15:42-50

1 Kọrinti 15:42-50

42
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a sí jì í dìde ni àìdíbàjẹ́.
43
A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì jí í dìde ní agbára.
44
A gbìn ín ni, ara ẹran a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí. Bí ara ẹran bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ.
45
Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a”; Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè.
46
Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.
47
Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.
48
Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.
49
Bí àwa ti rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àwòrán ẹni ti ọ̀run.
50
Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options