1 Kọrinti 10:27-33
27
Bí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àsè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àsè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn.
28
Bí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn.
29
Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn.
30
Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.
31
Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.
32
Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run.
33
Bí mo ṣè n gbìyànjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà.
Settings