1 Kronika 4:38-43
38
Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn. Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi,
39
wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn.
40
Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
41
Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn.
42
Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri.
43
Wọ́n sì pa àwọn ará Amaleki tí ó kù, àwọn tí ó ti sálà, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
Settings