Skip to content
1 Kronika 19:14

1 Kronika 19:14

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 14 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
11
Ó fi ìyókù àwọn ọkùnrin náà sí abẹ́ àkóso Abiṣai arákùnrin rẹ̀, a sì tẹ́ wọn kí wọn dojúkọ àwọn ará Ammoni.
12
Joabu wí pé tí àwọn ará Siria bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ammoni bá le jù fún ọ, nígbà náà èmi yóò gbà ọ́.
13
Jẹ́ alágbára kí ẹ sì jẹ́ kí a jà pẹ̀lú ìgboyà fún àwọn ènìyàn wa àti àwọn ìlú ńlá ti Ọlọ́run wa. Olúwa yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.
14
Nígbà náà Joabu àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀ lọ síwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Siria. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú rẹ̀.
15
Nígbà ti àwọn ará Ammoni ri pé àwọn ará Siria ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin rẹ̀ Abiṣai. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu padà lọ sí Jerusalẹmu.
16
Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Siria rí wí pé àwọn Israẹli ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Siria rékọjá odò Eufurate wá, pẹ̀lú Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun Hadadeseri, tí ó ń darí wọn.
17
Nígbà tí a sọ fún Dafidi nípa èyí, ó pe gbogbo Israẹli jọ wọ́n sì rékọjá Jordani; Ó lọ síwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n. Dafidi fa ìlà rẹ̀ láti bá àwọn ará Siria jagun wọ́n sì dojú ìjà kọ ọ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options