1 Kronika 16:23-33
23
Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
24
Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.
25
Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ jùlọ; òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ.
26
Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà, ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
27
Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀; agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀.
28
Fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa.
29
Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀; gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀. Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.
30
Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé! Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i.
31
Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”
32
Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀; Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀!
33
Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin, wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa, nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé.
Settings