Skip to content

Saamu3

Ìṣòro àti ẹ̀gàn

1
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu. Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí apata mi

3
Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4
Olúwa ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

Ìsùn àlàáfíà láàrín ewu

5
Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6
Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

Àdúrà fún ìgbàlà Ọlọ́run

7
Dìde, Olúwa! Gbà mí, Ọlọ́run mi! Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n; kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8
Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá. Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options