Fò sí àkóónú

Saamu12

Ẹ̀bẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn ẹlẹ́tàn

1
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́; olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
2
Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀; ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.
3
Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
4
tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa; àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”

Ìlérí OLÚWA láti ṣiṣẹ́

5
“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní, Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”
6
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù, gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀, tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìpamọ́ Ọlọ́run

7
Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́ kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
8
Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options