Saamu123
Listen to this chapter
0:00
0:00
1
Orin fún ìgòkè. Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.
2
Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3
Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4
Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Options
Study Note