Saamu114
Listen to this chapter
0:00
0:00
Ọlọ́run Ṣamọ̀nà Ísírẹ́lì Jáde Kúrò ní Íjíbítì
1
Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
2
Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba.
Ìṣẹ̀dá Fèsì Sí Wíwà Ọlọ́run
3
Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn.
4
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
Ìbéèrè Fún Ìṣẹ̀dá
5
Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
Wíwà Olúwa Ń Béèrè Ẹ̀rù
7
Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
8
tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Reading Width chars
Options
Study Note