Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Zimri: 1. A chief of Simeon

4 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa 1. A chief of Simeon

  1. Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé.

  2. Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.

  3. Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró;

  4. Orúkọ ọmọ Israẹli tí a pa pẹ̀lú obìnrin Midiani náà ni Simri, ọmọ Salu, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Simeoni.