Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Weaving

11 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrín rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìṣẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.

  2. Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti aláṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunṣọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà àti ayàwòrán ń ṣe.

  3. Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù efodu gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ aláṣọ híhun,

  4. Fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ aláṣọ híhun.

  5. ó sì fi ìhunṣọ dè wọ́n. Ó sì tún pè é pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.” Òun sì jí ní ojú oorun, ó sì fa ìdè ìhunṣọ náà tu pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀.

  6. Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ.

  7. Ó sì wó ibùgbé àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún òrìṣà Aṣerah.

  8. Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀.

  9. “Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ, o sì di lílò ní àìní ìrètí.

  10. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

  11. Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà; ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.