Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Toe: Anointed in consecration
Àwọn ẹsẹ nípa Anointed in consecration
Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká.
Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.
Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.