Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Timbrel: Used in religious service

6 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Used in religious service

  1. Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali.

  2. Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè.

  3. Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn; àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn.

  4. Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá, tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

  5. Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀ jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

  6. Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,