Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Excellency and Glory of the Church: God delights in
Àwọn ẹsẹ nípa God delights in
Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa, adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro. Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba, àti ilẹ̀ rẹ ní Beula; nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.