Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tears: Observed by God
Àwọn ẹsẹ nípa Observed by God
Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omijé mi sí ìgò rẹ, wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
“Rántí, Ìwọ Olúwa, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.
Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Isaiah wá pé,
“Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé, Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ.