Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shedeur
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
“Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí: “Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
Ní ìhà gúúsù: ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
Elisuri ọmọ Ṣedeuri olórí àwọn ọmọ Reubeni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin.
màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn.