Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Miter

10 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù efodu, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Aaroni arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

  2. “Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fínfín èdìdì àmì pé. Mímọ́ sí Olúwa.

  3. Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà; kí ó sì wà níwájú fìlà náà.

  4. Kí ó wà níwájú orí Aaroni, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Aaroni nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.

  5. “Ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára ṣe fìlà. Ìwọ yóò sì fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ọ̀já àmùrè.

  6. Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

  7. Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elése àlùkò àti òdòdó tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

  8. Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì: Mímọ́ sí Olúwa.

  9. Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  10. èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.