Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Meremoth: 1. A priest who was appointed to weigh and register gold and silver vessels brought to Jerusalem
Àwọn ẹsẹ nípa 1. A priest who was appointed to weigh and register gold and silver vessels brought to Jerusalem
Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Meremoti ọmọ Uriah lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Eleasari ọmọ Finehasi wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi; Josabadi ọmọ Jeṣua àti Noadiah ọmọ Binnui wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Meṣullamu ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn mọ. Bákan náà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sadoku ọmọ Baanah náà tún odi mọ.
Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin rẹ̀.