Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Melchishua

5 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Àwọn ọmọ Saulu sì ni Jonatani, Iṣifi àti Malikiṣua. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Merabu àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Mikali.

  2. Àwọn Filistini sì ń lépa Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Filistini sì pa Jonatani àti Abinadabu, àti Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu.

  3. Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.

  4. Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba a Saulu, àti Saulu baba a Jonatani, àti Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.

  5. Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua.