Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mark: Paul and Barnabas contend concerning
Àwọn ẹsẹ nípa Paul and Barnabas contend concerning
Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”
Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku.
Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.
Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì, Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi.