Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Iconoclasm

6 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí Olúwa Ọlọ́run yín.

  2. Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má ba à di ẹni ìparun bí i rẹ̀. Ẹ kórìíra rẹ̀ kí ẹ sì kà á sí ìríra pátápátá, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni.

  3. Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà àti òfin tí ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra láti máa tẹ̀lé, ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, fi fún un yín láti gbà: ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ náà.

  4. Gbogbo ibi gíga àwọn òkè ńlá, àti òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ ó lé jáde, tí ń sin òrìṣà wọn ní kí ẹ mú kúrò pátápátá.

  5. Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, ẹ bi òpó ìsìn wọn ṣubú, kí ẹ sì sun òpó Aṣerah wọn ní iná. Ẹ gé gbogbo ère òrìṣà wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ ní gbogbo ààyè wọn.

  6. Ẹ kò gbọdọ̀ sin Olúwa Ọlọ́run yín bí i tiwọn.