Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Gourd: Jonah's, believed to be a vine resembling the American squash, used in Assyria to cover booths
Àwọn ẹsẹ nípa Jonah's, believed to be a vine resembling the American squash, used in Assyria to cover booths
Olúwa Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ.
Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.