Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Gold: Altar, lamps, and other articles made of
Àwọn ẹsẹ nípa Altar, lamps, and other articles made of
Solomoni sì túnṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú: pẹpẹ wúrà; tábìlì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà.
Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn-ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko; fìtílà àti ẹ̀mú wúrà;
ọpọ́n kìkì wúrà, alumagaji fìtílà, àti àwokòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára; àti àgbékọ́ wúrà fún ìlẹ̀kùn inú ilé Ibi Mímọ́ Jùlọ àti fún ìlẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹmpili.
Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa.