Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Gideon: He destroys the altar of Baal, and builds one to the Lord
Àwọn ẹsẹ nípa He destroys the altar of Baal, and builds one to the Lord
Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù baba rẹ, àní akọ màlúù kejì ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀.
Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o sì mú akọ màlúù kejì, kí o sì mú igi ère òrìṣà Aṣerah tí ìwọ bẹ́ lulẹ̀ rú ẹbọ sísun sí Olúwa.
Gideoni mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé baba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.