Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Deserts: Desolation by armies
Àwọn ẹsẹ nípa Desolation by armies
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.
A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀ tí kò wúlò níwájú mi, gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.
Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ ni àwọn apanirun ti gorí, nítorí idà Olúwa yóò pa láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà; kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.
Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká, wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn. Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín, nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.