Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Cymbal: Used in the temple service

2 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Used in the temple service

  1. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà-oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tuntun wọ́n ń lo kimbali, dùùrù àti ohun èlò orin olókùn. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfáà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn.

  2. Àwọn afùnpè àti àwọn akọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan ṣoṣo, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun Olúwa. Wọ́n fi ìpè, kimbali àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sókè láti fi yin Olúwa, wọ́n ń kọrin pé, “Ó dára; ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.” Nígbà náà ni ìkùùkuu ojú ọ̀run kún inú tẹmpili Olúwa,