Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Cowardice

4 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. “ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín.

  2. Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín.

  3. “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

  4. tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?