Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Cannibalism
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ìwọ ó sì jẹ èso ọmọ inú rẹ̀, ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ti àwọn ọmọ rẹ obìnrin tí Olúwa Ọlọ́run ti fi fún ọ; nínú ìdótì náà àti nínú ìhámọ́ náà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò há ọ mọ́.
Ọkùnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, ojú rẹ̀ yóò korò sí arákùnrin rẹ̀ àti sí aya oókan àyà rẹ̀, àti sí ìyókù ọmọ rẹ̀ tí òun jẹ kù.
Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìhámọ́, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ gbogbo.
Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin,
àti sí ọmọ rẹ̀ tí ó ti agbede-méjì ẹsẹ̀ rẹ̀ jáde, àti sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí yóò bí. Nítorí òun ó jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí àìní ohunkóhun nínú ìdótì àti ìhámọ́ náà, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ.
Nígbà náà ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’
Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.”