Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ananias: 3. A Christian in Damascus

14 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa 3. A Christian in Damascus

  1. Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Damasku, tí a ń pè ni Anania! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Anania!” Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”

  2. Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Judasi ní òpópónà Tààrà, kí ó sì béèrè ẹni tí a ń pè ni Saulu, ara Tarsu, sá wò ó, ó ń gbàdúrà.

  3. Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Anania, ó wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”

  4. Anania sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúròó ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búburú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerusalẹmu.

  5. Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”

  6. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Máa lọ; nítorí ohun èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Israẹli.

  7. Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”

  8. Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”

  9. Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀.

  10. “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Anania tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀.

  11. Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Saulu, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì ṣí ojú sí òkè mo sì lè rí i.

  12. “Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀.

  13. Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́.

  14. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè? Dìde, kí a sì bamitiisi rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pe orúkọ rẹ̀.’