Skip to content

Meshullam

3 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Meshullam

  1. Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Meṣullamu ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn mọ. Bákan náà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sadoku ọmọ Baanah náà tún odi mọ.

  2. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananiah ọmọ Ṣelemiah, àti Hanuni ọmọ ẹ̀kẹfà Salafi, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Meṣullamu ọmọ Berekiah tún ọ̀kánkán òdìkejì ibùgbé ẹ̀ ṣe.

  3. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Juda ti mulẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekaniah ọmọ Arah (Sanballati fẹ́ ọmọ Ṣekaniah), ọmọ rẹ̀ Jehohanani sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Meṣullamu ọmọ Berekiah.