Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Righteousness of God: Acknowledge, though the wicked prosper
Àwọn ẹsẹ nípa Acknowledge, though the wicked prosper
Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí, ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.
Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.
Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi,
títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.
Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkígbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?