Sekariah 2:6-9
6
“Wá! Wá! Sá kúrò ni ilẹ̀ àríwá,” ni Olúwa wí, “nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín káàkiri,” ni Olúwa wí.
7
“Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, ìwọ Sioni, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Babeli gbé.”
8
Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀.
9
Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.
Settings