Sekariah 13:7-9
7
“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká: èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké.
8
Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí, “a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú; ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.
9
Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò: wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn: èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’ àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”
Settings