Skip to content
Sekariah 10:6-12

Sekariah 10:6-12

6
“Èmi o sì mú ilé Juda ní agbára, èmi o sì gba ilé Josẹfu là, èmi ó sì tún mú wọn padà nítorí mo tí ṣàánú fún wọn, ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tì í ta wọ́n nù; nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi o sì gbọ́ tiwọn
7
Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì: àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.
8
Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ; nítorí èmi tí rà wọ́n padà; wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.
9
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè: síbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jíjìn; wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà.
10
Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Asiria. Èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi àti Lebanoni; a kì yóò sì rí ààyè fún wọn bí ó ti yẹ.
11
Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já, yóò sì bori rírú omi nínú Òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀, ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò.
12
Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa; wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,” ni Olúwa wí.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options