Orin Solomoni 8:8-14
8
Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
9
Bí òun bá jẹ́ ògiri, àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn, àwa yóò fi pákó kedari dí i.
10
Èmi jẹ́ ògiri, ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀ bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.
11
Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún (1,000) fàdákà.
12
Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi; ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.
13
Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ, jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!
14
Yára wá, Olùfẹ́ mi, kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín, lórí òkè òórùn dídùn.
Settings