Skip to content
Orin Solomoni 8:5

Orin Solomoni 8:5

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 5 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
2
Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi. Èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu, àti oje èso pomegiranate mi.
3
Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.
4
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà. Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè. Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.
5
Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀. Olólùfẹ́ Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.
6
Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.
7
Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.
8
Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options