Orin Solomoni 7:1-5
1
Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà. Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2
Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama tí a fi lílì yíká.
3
Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4
Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.
5
Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká, bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
Settings