1
Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin? Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí a lè bá ọ wá a?
2
Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀, sí ibi ibùsùn tùràrí, láti máa jẹ nínú ọgbà láti kó ìtànná lílì jọ.
3
Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.