Romu 4:5-16
5
Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo.
6
Gẹ́gẹ́ bí Dafidi pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́.
7
Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
8
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.”
9
Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.
10
Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni.
11
Ó sì gbé àmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú.
12
Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà.
13
Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́.
14
Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá jẹ ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára.
15
Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú, ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀.
16
Nítorí náà ni ó ṣe gbé e ka orí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-ọ̀fẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú-ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Abrahamu, ẹni tí í ṣe baba gbogbo wa pátápátá,
Settings