1
A sì fi ìfèéfèé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá-ìwọ̀n: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹmpili Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀.
2
Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì (42).