Saamu 89:46-51
46
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé? Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?
47
Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
48
Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀? Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?
49
Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà, tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
50
Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ; bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
51
ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa, tí wọn gan ipasẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
Settings