Saamu 88:8-16
8
Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn. A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
9
ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú. Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́; mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10
Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi? Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11
A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí, tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12
A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
13
Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa; ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14
Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
15
Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú; nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí, èmi di gbére-gbère.
16
Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi; ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò.
Settings