Saamu 72:4-14
4
Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5
Àwọn òtòṣì àti aláìní yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn, yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
6
Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀, bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀.
7
Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà; títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
8
Yóò máa jẹ ọba láti òkun dé òkun àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
9
Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10
Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù wọn yóò mú ọrẹ wá fún un; àwọn ọba Ṣeba àti Seba wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11
Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
12
Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13
Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14
Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.
Settings