1
Dá mi láre, Ọlọ́run mi, kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè: yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
2
Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi. Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀? Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́, nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?