Saamu43
Listen to this chapter
0:00
0:00
Ẹ̀bẹ̀ fún ìdáláre àti ìgbàlà
1
Dá mi láre, Ọlọ́run mi, kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè: yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
2
Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi. Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀? Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́, nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
Àdúrà fún ìmọ́lẹ̀ àti ọ̀nà sí tẹ́mpìlì
3
Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde, jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí; jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ, sí ibi tí ìwọ ń gbé.
4
Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run, sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi, èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù, ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
Ìyànjú sí ìrètí nínú Ọlọ́run
5
Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí? Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi? Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run, nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Reading Width chars
Options
Study Note