Saamu 39:1-6
1
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi. Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀; èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
2
Mo fi ìdákẹ́ ya odi; mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere; ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
3
Àyà mi gbóná ní inú mi. Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn; nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
4
“Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
5
Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ. Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
6
“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
Settings